Olanrewaju spiritual HOME

Olanrewaju spiritual HOME A SPIRITUALIST ⚕️
A HERBAL PHARMACIST 🌿

OSE ATUDE, WEGUN WEPE ,WE ISHE ,WE OSHI ,PROMISE AND FAILURE, CORB WEB.. Metalokan niiiEgbo Tude  #50Eepo obo dieAta ijo...
04/08/2026

OSE ATUDE, WEGUN WEPE ,WE ISHE ,WE OSHI ,PROMISE AND FAILURE, CORB WEB.. Metalokan niii

Egbo Tude #50
Eepo obo die
Ata ijosin 9 fun okunrin 7 fun obirin
Ao gun papo Mon ose dudu ao fi hot schnapps po papo.. Ao kosinu ike funfun,

Lilore
Ao ma fi omi gbigbona we laaro lale, ao koko fi epo para ki a to mawe..

Laarin ojo 4 a o dupe lowo olodumare..

Iwo ti oba fe se ise yii tio sii fe koje fun E
Dupe lowo olodumare kosi shadura funmi
Olanrewaju spiritual HOME
08087432197....

Eku ojumo -oju mo ire ojumo idunu ni yio je fun enikokan wa lase edumare Eje kín funyin ni eleyi lati fibò gbogbo idiwọ ...
04/08/2026

Eku ojumo -oju mo ire ojumo idunu ni yio je fun enikokan wa lase edumare
Eje kín funyin ni eleyi lati fibò gbogbo idiwọ \ ide yi kuro lọrùn yin, ao sì di ọmọ tuntun ninu \ eda tuntun.

OOGUN ATUDE ASINA AWON AGBA TI O TUN NṢIṢẸ ISORI FUN ODUN TUNTUN

Epo obo, eru alamo.

Ao lọ eroja méjèèjì lotooto ni ori olo otooto , ao wa dáa papọ. Ao tẹ ni ifa irosun ọsẹ .
Ao pé gbólóhùn rẹ sí ,

LILO RE
Lẹyìn tí a bá ti pé gbólóhùn rẹ sí tan, ao kọkọ fi singbere sí orikerike arawa ni mẹta mẹta . Ao ṣẹṣẹ wa poo iyokù mọ ọsẹ , ao ma fi wẹ lẹyìn ọjọ kẹta ti a singbere yí.

Bi ao se see niyi.....

Ti a ba fe wẹ , ao kọkọ fi èpo pupa pa gbogbo ara wa , ao wa mu ada (cutlass ) tuntun tàbí aloku losi baluwe , ao duro sori ada yen.

Ọjọ méje ni ao fi wẹ ọsẹ yi pelu kainkain tuntun méje !
Ti o ba ti pe ọjọ méje , ao koo gbogbo kainkain yen, ao lọ dáa won s**o tonsan .

NOTE.... ìwe yi ko gbudọ jaa rara o. Ti o ba jaa , ao gbudọ wẹ Mọ óò.

GBÓLÓHÙN RẸ NIYI....

Ari oori 3* Amoori 3*, oge mowo 3*, idandan aboju dare dare. Àjòjì kìí wòlú kofi ikangun se itana owó. Àwọn ní wọn ní ẹyẹ mejeeje ti nbe lóde òrun , tí wọn bani ki t'ayé o pani jẹ titaye a ma panije.

Ti wọn bá ní ki titaye o saanu ẹni , titaye asi saanu ènìyàn. Emi lágbájá ọmọ lágbájá
Modi ọmọ ẹyẹ ode òrun lóni ,eru ni kofi ruu gbogbo aburu àrà mi danu .
òsó ní moba bẹ tóní ohùn koni gbà ebemi obo ni ki obami bọ lọ sode orun.

Aje ni moba ba bẹ tóní ohùn koni gbà ebemi obo ni ki o bami bọ lọ s'ode òrun.
Emi lagbaja ti moba singbere yi asala ni ki e je ki nsin asinla ni koje fun mi.

Asin sorire ni koje fun mi. Emi lagbaja ti moba sin gbere yi ki ma sin lasinla o, irosun ọsẹ oo bámi sìn gbogbo aburú ará mi danu. Irosun ọsẹ, bami sin ẹjẹ ikorira ará mi danu. bami sin idiwọ ayé mi danu kin di olowo kin di olókìkí ninu ayé .

oogun yi daju gidigidi óò
Majemu re ; iwure fun mi ⚕️
Lati owo oludasile Olanrewaju spiritual HOME
Fun eyikeyi ise ekan simi sori ero ipe mi tabi whatapp mi

08087432197

01/07/2026

Quick tip and notice for the new month of July 2026 🌿🙏🏽

DM me on a call | WhatsApp if you need anything ; 08087432197

25/06/2026

A brief summary of a spiritual message to avoid something black {nkan dudu} 🌿⚕️

Contact & Whatsapp me on this number - if u need any spiritual guardiance or herbal medicine
08087432197
Olanrewaju spiritual HOME

20/06/2026

Reason why prayer {adura | iwure} & effort {igbiyanju | isapa} delay before accepting.
⚕️🕊️🌿

PART 2

16/06/2026

Reason why prayer {adura | iwure} & effort {igbiyanju | isapa} delay before accepting.
⚕️🕊️🌿

PART 1

Adura gbogbo wa yi o gba - a o ni se lasan lase edumare Olanrewaju spiritual HOME Momu ise nla yi wa funwa ni  EYONU ASI...
12/06/2026

Adura gbogbo wa yi o gba - a o ni se lasan lase edumare
Olanrewaju spiritual HOME
Momu ise nla yi wa funwa ni
EYONU ASINA OWO GIDI......abo adie dudu kan, kowe kan original, ata senbaye abokan, padi atare kan.
Ao la adie yen legbe ni aaye, ao ti kowe yen bo ti yio wole, ao wa fi atare yen na sibe. Ti a ba riran pada ale ran ti ao ba riran koburu. Ao wa da ata yi sinu ikoko tuntun, ao wa fi eyin adie ti ako awon eroja silegbe yi le ori ata yi, yio siju soke. Ao jo papo. Ao lo daada. Ao ma fi fokomun tabi omi lasan loo ni dede ago mejila oru. Ao ma pe gbolohun re si..
Offo re... Kowe ni tufo oku eyin to laye elore soro emi l omo l fun awon olowo nlanla ilu yi ati okere ki won magbe owo nlanla fun mi lati ma fi be mi ni ise ti mon se..,
kosi eni tiko le lo ise yi.. Hair dresser, alfa, contractor ati gbogbo onise owo pata ..awon agba ni won o ma polowo re kiri., ogun nla nio . Danwo.

Ise awon agbalagba todaju ni ooo
Ele pemi sori number yi tabi bami Lori whatapp
08087432197

09/06/2026

Olanrewaju spiritual HOME mojuba awon ajunilo ,mojuba awon agbalagba ,ejeko ju mi seee oooo
Eyi ni ise awon agba todaju dada - tosi munadoko

OOGUN ẸBE AWON AGBÀ TI ONA ENIYAN FI NLA
Abo adie dudu 1, epo obo to gboo daada , ata ijosi 16 tabi jubẹlọ , atare odindi kàn , isasun nla tuntun , ọsẹ dúdú .

ṢÍṢE RẸ
Ao lọ èpo obo lọtọ, ata ijosi lọtọ, ao wa poo mo ọsẹ dúdú, ao koo sibi kan.

Ao fi atare sí abiya adiẹ sí abiya osi adiẹ náà, ao kaa ori rẹ sí abiya ọtún, ao kaa ẹsẹ rẹ mejeeji mo lára, ao wa gbe sinu isasun yen, ao fi ọsẹ ti a gun nkan mo yen boo mole laaye ti koni hàn mọ, ao fi ideri rẹ dee pàá mobe. Ao wa gbe sinu asunhan aṣọ funfun , ao lọ ri mọle fún ọjọ méje gbáko.

Ni ọjọ keje yi , ao lọ huu isasun yi jade , ao wa sí ideri isasun yi, ao koo ọsẹ kuro lori adiẹ yen. Ao wa Gun adiẹ yeni kùnà dàada, ao po mo ọsẹ tuntun míràn , ao Gun kùnà gidi, ao ṣẹṣẹ wa poo papọ mo ọsẹ ti a kòó kuro lori rẹ. Ao wa kòó ọsẹ yi sinu isasun yen pada , ao gbèè sí ààyè ọwọ.

LILO RE
Ao ma wẹ ọsẹ yi ni alé pátá pátá ti a ba fẹ sun. Ao gbudọ jade mọ. Ọ daju tààrà.

Hmm....eyin ènìyàn mi , oogun ẹbe itusile gidi ni mo fún yín lóni , é lo gbìyànjú rẹ ki é mo wipe Elédùà sí ngbo adura olododo !

Oríṣi nkan ni oogun yi nṣiṣẹ fún . Bi àpẹẹrẹ

Ọ nṣiṣẹ asina
Ọ nṣiṣẹ atude
Ọ nṣiṣẹ ẹbe
Ọ nwoo àìsàn eniti awon agba nbinu sí
Ọ tun nṣiṣẹ ẹrọ asasi .
Koda yíò tun ṣiṣe miran lara rẹ yato sí àwọn nkan ti mo kọ sita yi. Oogun ayé àtijó ni.

Ese iwure fun mi Lori ise yi -ti eba si fe ki n bayin se epe mi sori ero ipe mi
08087432197

Eku ojumo oni Ise yi okunrin nikan lole lo Ise ijagun fun akoni ni ,alagba ati lati lati bori eyikeyi isoro ti aba n koj...
08/06/2026

Eku ojumo oni
Ise yi okunrin nikan lole lo
Ise ijagun fun akoni ni ,alagba ati lati lati bori eyikeyi isoro ti aba n koju
Ise todaju ni taara .... IFA AKIN ORO....
Odindi adan kan, epo igi idi, odindi atare kan, ao jo po, ao ro sinu ado ato tabi seere. Ao pa akuko adie kan fun, ao fi eje re yi ara ado yi, ao tu huhu re die die, ao le mo ara ado yi...
Ti aba ti fe lo, ao bu die, ao te ifa re si (akin oro) ao pe ofo re si, ao fi epo pupa la tabi ki a fi fokomu..
OFFO RE... Akin oro awo ori ogun, apo sese awo ode ore,odidikurudi awo ori olofin, bioyi awo ode igbariri. Awon mererin omokofa orunmila ni won nse, orunmila kowon nifa na t**i, won mo ifa na tan, won ni orunmila lawon o koko sa ifa na pa.
Orunmila wa sare t**i, osare lo s**o munimuni ti sawo ile alara, osare lo s**o esu gegele ti sawo alale oja, osare lo s**o orisanla eyi ti o toju orere lapa.
Won ni baba kinnile o kiri ? O ni akin oro awo ori ogun ni, oni aposese awo ode ore ni, oni odidikurudi awo ori olofin ni, oni bioyi awo ode igbariri ni.
Won ni baba kin lo se fun won ? Oni awon mererin omokofa oun ni won nse, oni oun kowon nifa na t**i, won mo ifa na tan, won ni oun lawon o koko sa ifa na pa..
Won wa ni ki baba o toju eye adan kan, odindi atare kan,won ni igi ifa kan toku, awon o fi kun fun baba, won ni ki baba o jo po, koma to sepola, kio ma fi fokomu.
Baba tun se be tan, otun sare lo s**o munimuni ti sawo ile alara, otun sare lo s**o esu gegele ti sawo alale oja, otun sare lo s**o orisa nla eyitoti oju orere lapa.
Won ni baba, kini tun le o kiri ? Oni akin oro awo ori ogun ti ku, oni aposese awo ode ore tiku, oni odidikurudi awo ode olofin tiku, oni bioyi awo ode igbariri tiku.
Omode ni, agba ni ,okunrin ni, obinrin ni, alafa ni, oso ni, aje ni, to ba lohun o se emi LOL...(aniyan).
Baba wa yanu koto, orin awo lo ko si baba lenu, baba ni bi oso ile ba ke roo ti won ko gbin, ti aje ile ba ke roo tiwon ko foun, igbe iku o kan mi leye adan nke loko....{ adan dee alaro eye, adan dee o alaro eye o, igbe iku o kan mi leye adan nke loko...hmm ifa nla ni ifa yi, kosi oun ti ko kapa. Ida gidi ni lodo awo agbalagba !

Akin Oro(Ogundabirete) Ogunda lotun, Irete losi ni wonpe ni Akin Oro
! !
! !
!! !
! !!
Esadura fun mi kobaleje fun yin Olanrewaju spiritual HOME
Yi o ma ju wa se ooo
08087432197

Ako ko mi re ejeko jumi se ,emi Olanrewaju spiritual HOME juba gbogbo eyin ajuni lo ,eledumare iba re .Ipese awon agbala...
07/06/2026

Ako ko mi re ejeko jumi se ,emi Olanrewaju spiritual HOME juba gbogbo eyin ajuni lo ,eledumare iba re .
Ipese awon agbalagba ni mo muwa funwa
O nsise asina tara O nsise ki a le ri owo O nsise ipo dunduno nsise ki a yo eniyan kuro lewon O nsise akoya
O nsise ki a lee ni promotion nibi ise
O nsise iferan tabi isopo ife laarin okunrin ati obinrin.
O nsise ki eniyan o ri contract gba
Kosi nkan ti a doju re ko ti ko ni see
........IPEESE AKEEKAKAKA TODAJU........
Eran malu ekiri kan ti o tobi die, awo ip*ese tuntun, iyere osun, obi ifin alawe merin. Opon ifa tabi paper funfun.
Sise re.....ao da iyereosun yen sori opon ifa tabi inu paper funfun, ao te ni odu osa meji. Ao fi obi yi si iwaju iyereosun ti o te lodu yi ninu opon ifa. Ao wa pe offore si....
Ti a ba ti p*e si tan, ao wa da sori eran malu yi ninu awo ip*ese.ao wa da ogeere epo pupa lee lori. Ao pa obi yi, ao fi beere ibi ti ao gbe ip*ese yi lo ti won o fi gba lowo wa. Ao gbe losi ibe ni ago mewa ale tabi mokanla. Ti o ba di aro ojo keji ni idaji kutu, ao lo gbe awo wa pada...
OFORE:Ake kakaka wolu 3*, Abirin kakaka wolu3× A gbe ori iroko ke kakaka 3*, Ibiti edarisi ni edari si 3*, ibiti e pin jeki si lepin jeki 3*, Eyin ni igba Erin ri tiwon nfi eyin lu eyin omo opere opere 3*, Eyin ni igba efon ri tiwon nfiiwo lu Iwo omo ogbangandanran ogbangandanran 3*, Eyin naa ni igba olopere ri tiwon fi iye nfo janpe janpe kalu 3*, Ewa ni kinni igba Erin ri tiwon fi nfi eyin lu eyin omo opere opere, Eni kinni igba efon ri tiwon fi nfiwo luwo omo ogbangandanran, Ewa ni kinni igba olopere ri tiwon fi iye fo janpe janpe kalu Ero!ero!! Ero!!! Seese lodifa fun koowe ajedo eniyan mabi, Aje oronro masinto, Eewo ni aje ko gbodo pa omo koowe, je ki aje mapa emi(L/L)ooo Kiwon lo Lana rere gbogbo owo nlanla fun mi lati oni lo nio. Nitoripe agbadikaka loruko tanpe ifa orunmila, ninu gbogbo eye to nfo radiradi loju orun, eyin iyami osoronga ati okanlerugba irunmole, loba olodumare pinhun lode orun. Won ni ki olodumare fowo mu ode orun ko yonda ile aye fun awon, olodumare fowo mu ode orun osi yonda ile aye fun yin. Nigbati e dele aye tan, eyin iyami osoronga tunwa ba orunmila pinhun wipe ki orunmila fowo mu aaro ati osan Awon ni awon ni oru. won niti orunmila bati pese fun awon loru, awon yoo mase gbogbo nkan toba fe fun laro ati losan. orunmila wa biwon lere wipe kinni ohun ipese naa ? won niki orunmila mafi eran abeje malu ekiri kan pelu iyereosun pese fun awon. toba ti pe oruko awon awon yo mase gbogbo ohun tobafe fun. Ipese ti eniki orunmila se lojo kinni anaa, ni emi L omo L se fun yin loni yio. Ti o base wipe lododo ati lotito leba nbe lode isalu aye yi, ki e wa lo pese gbogbo ohun ti mo bere funmi ni kiakia bayi o. ao wa se adura pelu aniyan wa.
Odaju oo

Se iwure fun mi kolebaje fun e - a o ni ri ija aye ooo
08087432197

Address

23 Lawrence Ilori Street Joju Bus Stop
Sango Otta
112212

Telephone

+2348087432197

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Olanrewaju spiritual HOME posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Olanrewaju spiritual HOME:

Shortcuts

Share